Ezekiel 25:15-17

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Filistia

15 a“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará Filistini hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Juda run, 16nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Filistini, èmi yóò sì ké àwọn ará Kereti kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run. 17Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.’ ”

Copyright information for YorBMYO